ṢÍṢE ÀFIHÀN AMAwuli
AMAwuli Shule ya Sababu jẹ́ ilé ìwé aládáni ojojúmọ́, tí kìí ṣe ọ̀fẹ́ẹ́, tí o npèsè ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti ọdún marun (5) sí ọdún mẹ́jọ (8). Ó jẹ́ ìgbàgbọ́ wa pé ìlànà ètò ẹ̀kọ́ tó dára jẹ́ ṣíṣe ìgbéradì sílẹ̀ fún kíkópa nínú iṣẹ́ ṣíṣe tí o dára jùlọ gẹ́gẹ́ bíi ènìyàn tí o ní ìtọ́sọ́nà tí o fojúhàn àti ìdí, àti fún ọmọ ní AMAwuli, èyí jẹ́ ìwúlò fún ipò àgbà. Irú ètò ẹ̀kọ́ alákọ́kọ́ tí AMAwuli pèsè láti ṣe ìrànwọ́ fún irú èròngbà ọkàn tí o ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìbáraẹnimu àti ní pípèsè ìgbéga ìgbésí ayé ìtọ́sọ́nà. Àwọn ọmọdé ma nkọ́ láti jẹ́ aládáni àti ìdáraẹnilójú ní ṣíṣe ìlépa takun-takun fún ìdàgbàsókè, jíjẹ́, àti láti farada ìdojúkọ, kíkọ́ ẹ̀kọ́ nínú àwọn ìfàsẹ́hìn àti wíwá àti / tàbí pípèsè àwọn ààyè fún ìtẹ̀síwájú àti ṣíṣe dáradára! N’ìdí èyí, fún ẹbí tí wọ́n nífẹ̀ sí àwọn àfojúsùn wọ̀nyí nípa pínpínú ibití ọmọ wọn yío tí ṣe ìmúrasílẹ̀ wọn sí ọ̀nà láti di àgbà, gbọdọ̀ jẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀nù, ìpinnu pípé, àti ìfarajìn pàtàkì.
ÀWỌN Ẹ̀KỌ́: ÀKÓPỌ̀ àti ÌTỌ́SỌ́NÀ
Ètò ẹ̀kọ́ ní AMAwuli Shule ya Sababu (AMASS) nkọ́ ìpinnu tó dá lórí ìbámu ìpìlẹ̀ alágbára pẹ̀lú ìpinnu ìwà
rere, àwọn èyí tí ó jẹ́, Heshima, Kujali, Jukumu. Àwọn alábàṣiṣẹ́pọ̀ ètò ẹ̀kọ́ AMASS ní ìwúrí fún àkíyèsi ara
ẹni àti ìdarí ara ẹni, pẹ̀lú èyítí àwọn akẹ̀kọ́ fi nṣe àwòkóse ọgbọ́n ní èrò, òye, àti ìpinnu. Nípasẹ̀ fífún ni
àyíká tó rọrùn, ètò ẹ̀kọ́ AMASS jẹ́ pàtó nínú gbogbo ìpinnu rẹ̀ láti ṣètò àwọn akẹ̀kọ́ láti jẹ́ olùṣe àti àwọn
olùtánṣòro pẹ̀lú ìmọ̀ agbára ara eni ìtara ìgbésí ayé làti lépa ìmọ̀ síwájú sii jú èyí tí wọ́n mọ lọ́wọ́lọ́wọ́.
ÌLÉPA àti ÌRAN
AMAwuli Shule ya Sababu nṣe ìtọjú ìpilẹṣẹ ọkàn t'ólóye tó dá lórí ìmọyì ènìyàn. Bákannán, ó ma nṣelè, láìsí dàrú-dàpọ̀, àti wípé fún àwọn ọmọdé kìí ṣe ọjọ́ iwájú nìkan ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ́ ọjọ́ iwájú èyítí wọ́n ti múra sílẹ̀ láti ṣe àtìlẹ́yìn fún nínú iṣẹ́ ìríjú wọn. Nítorínà, láti kọ́ ẹ̀kọ́ láàrín agbègbè yìí, jẹ́ ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ àwọn ìpìlẹ̀ tí Heshima (ọ̀wọ̀), Kujali (iyì), Jukumu (ojúṣe), àwọn ìran ọmọdé yío ní ìdàgbàsókè pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà; èyí tí yío jẹ́ bíi májẹ̀mu fún ìdíyelé ẹ̀kọ́; ní àjoṣepọ̀ pẹ̀lú ìbáramu; ṣíṣe àfikún ní rere sí àwùjọ àti wíwá ìmúṣẹ ní ìrírí ènìyàn fún ara ẹni àti fún àwọn ẹlò míràn.
Ọ̀RỌ̀ ÌYÀNJÚ LÁTI ẸNU OLÙDARÍ ÀGBÀ
Ẹ̀yin ẹbí àti ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n,
AMAwuli Shule ya Sababu (AMASS) ṣetán láti pèsè ètò ẹ̀kọ́ tí yío ṣe ìtọ́jú ìfarajìn sí ipa ọ̀nà ìdàgbàsókè ọgbọ́n pẹ̀lú ìpinnu pàtàkì ti ìmọ̀ ara ẹni nibití ìrònú, òye àti ṣíṣe ohun tí yío mú ọ̀nà àbáyo wà fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ pàtàkì sí gbígbé ìgbésí ayé tó n’ìtumò. Ní agbègbè tí ó ní àbójútó àti ìkóráeni níjanú, aní ìbárániṣepọ̀ tí ó dára nípasẹ̀ ìmọ̀ràn ti UBUNTU ìbásepò wa gẹ́gẹ́ bi ènìyàn jẹ́ àfojúsùn wípé “ ÈMI NI” nítorí wípé “ ÌWO NI” àti wípé bákanná pẹ̀lú ìwọ nítorí wípé “ÀWA NI” Nítorínà, Èmi pẹ̀lú ÌWO àti ÀWA ni ó di ÀWA níbití iṣẹ́ pàtàkì tí ẹnìkan ti sopọ̀ mo idamọ́ àti ojúṣe sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí o kàn gbogbo wa ní àpapọ̀. Títẹ̀lẹ́ ìtọ́nisọ́nà, ìlànà, àti ìbáraẹnisọrọ̀ láàrín gbogbo àwọn ẹgbẹ́ tí nse okùfà ìdàgbàsókè àti ìfọkàntán ìmúdúro ṣinṣin àti ìhùwàsí tí o tọ́. Ìwọ̀nyí ni a bèerè lọ́wọ́ àwọn tí a fi lé lọ́wọ́ láti kọ́ àti ṣe àabò ìlera ènìyàn, èyítí o bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú, ara ẹni. Láàrín ilé ìwé, ilé àti àwùjọ lápapòo, a ní àfojúsùn fún òye àjọṣepọ̀ àgbáyé wípé gbogbo ayé jẹ́ ọ̀kan. A ní ìgbàgbọ́ wípé ẹ yío tẹ́wọ́ gbà ìkóráeni níjanú àti àfojúsùn tí o ṣe okùnfà ìfarajìn fún ìdàgbàsókè àti àṣeyọrí láàrín àti ìtayọ ní AMAwuli Shule ya Sababu.
Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú iṣẹ́ pàtàkì,
Dr. A.K. Tosu, f.SHr.
Ìríjú Àgbà
Olùdarí Gbogbogbò
A KÍ Ẹ̀YIN ÒBÍ
Ìdúróṣinṣin lórí ìdì kan, ìfẹṣẹ̀múlẹ̀ sí iṣẹ́ ṣíṣe, àti àbojútó sí àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì sí AMASS ní ìbásepọ̀ àwọn ọdún tó tí kọjá, a ní ìgbẹkẹ̀lé wípé pẹ̀lú àkíyèsí ìríjú àti ojúse gẹ́gẹ́ bí òbí, àgbàlagbà, elétò ẹ̀kọ́ àti wípé àṣeyọrí wa lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtọ́nisọ́nà yío jẹ́ àlàyé kíkún nípasẹ̀ àwọn ìrírí ìgbésí ayé àwọn ọmọ wá sí ipò àgbà. A dúpẹ́ fún ìfarajìn yín fín ìpinnu láti ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ oní àti ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́bí obí tí o ní ọmọ (àwọn ọmọ) ní AMAwuli Shule ya Sababu, ẹ yío ní ànfàní sí ọ̀nà àbáwọlé ìtàkùn ayélujára àwọn òbí. Èyí ni yío jẹ́ ọ̀nà kan láti gba àlàyé gbogbogbò àti àlàyé kan pàtó, ní nígbàkannaà pẹ̀lú ìṣàkóso àwọn àdéhùn àjoṣepọ̀ nípa ọmọ (àwọn ọmọ). Pẹ̀lú àwọn àtẹ̀jáde déedé àti àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè, àwọn ìtọ́sọ́nà ìgbàdégbà yío wà lórí àwọn ọ̀nà àbáwọlé ìtàkùn ayélujára wọ̀nyí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìlosíwájú nípa lílò àwọn ohun èlò ní sáà ọdún ẹ̀kọ́ kọ̀ọkan. Ẹ yío tún ní ànfàní láti ṣe ìpàdé ojú-ko-ojú pẹ̀lú ẹ̀ẹka ẹ̀kọ́, àwọn òṣìṣẹ́, àti àwọn olórí ẹ̀ẹka ní àkókò tí o yẹ. Inú wa dùn nípa ọdún ẹ̀kọ́ kọ̀ọkan àti wípé anírètí láti jẹ́ kí àwọn nkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ pamoja (lápapọ̀)!
A kíi yín,
Àwọn Alákóso
ÀLÀYÉ
Láti béérè síwájú sii nípa gbígbaniwọlé? Jọ̀wọ́ yan ìpín tí o yẹ fún àlàyé.
Odún Marun - Mẹ́fà
Odún Méje - Mẹ́jọ
Quick Links
About
Admissions
Privacy Note